Ilà Kíkọ pẹ̀lú Ìtàn d'òwe---Àdàgbà kọlà ṣíso ní so


Ilà kíkọ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà dára wọn mọ nígbà ìwáṣẹ̀ àti fún oge ṣíṣe.

Orísun ilà kíkọ kan fiyé wa wí pé òwò ẹrú ló ṣe okùnfà ilà kíkó nílẹ́ Yorùbá.
Ṣùgbọ́n ìtàn kan sì tún fiyé wa wípé Ọba Aláàfin Ọ̀yọ́ ìgbà kan ló fẹ́ ṣe orò tàbí ohun tí a le pè ní ayẹyẹ kan fún ìyá rẹ̀, ó wá rán àwọn ẹrú rẹ̀ méjì kan lọ láti lọ sí ìlú ìyá rẹ̀ láti béèrè orúkọ ìyá rẹ. Ilẹ̀ Tàpá ni ìlú ìyá rẹ̀ ìgbà náà wà.
Nígbà tí àwọn ẹrú méjì yìí dé bẹ̀, wọ́n ṣe ayẹyẹ fún, wọ́n mu ọtí yó, látàrí èyí ọkàn nínú àwọn ẹrú náà ló rántí ìdí abájọ tí wọn ṣe rán wọn wá láti òde Ọ̀yọ́. Láì dé nà pa ẹnu, wọ́n béèrè orúkọ náà, wọ́n sì pe orúkọ ìyá rẹ ní TÓRÒSI. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n padà sí Ọ̀yọ́ ṣùgbọ́n àkókò tí ọba bi wọ́n, ọkàn kò rán tí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fàájì. Ẹrú kejì lọ rántí, tí ó sọọ́.

    Inú ọba dùn, ó wá wò ó pé ọ̀nà wo ni òun lefi ìyà jẹ ẹrú yí. Ó wá pàṣẹ kí wọn yaá ní nǹkan l'ójú. Nígbàtí ojú rẹ̀ san tán, wọ́n wá ri pé òun ni ó rẹwà jù lọ nínú àwọn ẹrú wọ̀nyí, bí ọba ṣe pàṣẹ kí wọn máa ya gbogbo wọ́n ní nǹkan l'ójú. Ọba Aláàfin ìgbà náà fẹ́ kọ ṣùgbọ́n àdàgbà kọ là kòdùn, nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbàlagbà tó kọ nígbà náà, ṣíṣo ní ó so. Kódà ìtàn yìí mú òwe Yorùbá kan jáde nígbà tí ó lọ báyìí wípé, Àdàgbà kọlà, síso ní so.
 
    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá lo tí ní ilà kan tí wọ́n kọ ní pàtó láti dá ara wọn mọ, kódà àwọn ìdílé mìíràn náà ni ti wọn bẹ́ẹ̀ náà ni ilà kíkọ ti di isé ìdílé àwọn kan tí wón pé orúkọ Ilé wọn ní Olólà.
 
     Èyí ilà ni Yorùbá máa ń kọ. Yorùbá má ń sá kéké ni, wọ́n máa kọ Pélé, wọ́n má ń bu Bàmú pẹlu àwọn mìíràn bí i Àbàjà, Gọ̀mbọ̀, Túrè, Kéké Olówu abbl.
 
    Òndó - | | bí bu ojú ni tiwọn.
    Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀ - Pélé ||| mẹ́ta mẹ́ta.
    Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀ - Bàmú
                 /
    ----------/
    ----------
    ----------
                 
                           | | |
    Gọ̀mbọ̀ | | | | | |
                   _____| | |
                    ______| |
                      _______|
    Yó wọnú agbárí, yóò parí ní àárín orí.
 
 
    Túrè | | |
              | | |
              | | | ¦¦¦
 
    Àbàjà Èkìtì - - - - - - -
                       - - - - - - - -
                       - - - - - - - -
 
    Àbàjà Olówu
   \ \ \
    \ \ \
     \ \ \ | | |
      \ \ \ | | |

                     





   
Àkójọpọ̀ rẹ wáyé láti owó,
AYANWUYI, Israel Temitope
Pẹ̀lú ikọ̀ AIF MEDIA nínú ẹ̀ka wọn ti,
#Yorùbá_dùn_lÉdè.
First edition 2013, Newly edited 2018.

0 comments:

Post a Comment

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA