Ìtàndòwe—Ìdóró gba ìkòkò ni Ìdóró gba idẹ



Ìtàndòwe—Ìdóró gba ìkòkò ni Ìdóró gba idẹ
Láti owó Israel Ayanwuyi, 2019

Ọ̀rẹ́ méjì kan wà nígbà àtijọ́, ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ ni àwọn méjèèjì nítorí pé wọ́n fẹ́ràn ara wọn púpọ̀. Nígbà kan ẹ̀wẹ̀, ìkan nínú wọn fẹ́ gbin obì, ó sì lọ tọrọ kòkò lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti fi dáàbò bò igi obì náà kó lè ba dàgbà àti kí ẹranko má le ba igi náà jẹ́.

Ọ̀rẹ́ kejì náà bí ọmọ obìnrin tí ó rẹwà ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n yẹ àkọsẹ̀jayé ọmọ náà, wọ́n ri pé ẹlẹ́mìí kúkúrú ni àyàfi bí wọ́n bá rí idẹ tí wọn yóò fi ṣe gbékúdè fún ọmọ obìnrin náà. Ọ̀rẹ́ yí lọ yá idẹ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó yá ní ajádí ìkòkò láti fi gbin igi obì wọ́n sì fi idẹ yí sí ọmọ náà lọ́rùn kí ó má baà kú ṣùgbọ́n nígbà tí igi obì yí dàgbà tí ń so ogún, ọgọ́rùn-ún àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ìlara gbé ọ̀rẹ́ tí ó yá ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ìkòkò yí wọ̀.

Ọ̀rẹ́ yí ní òun yóò gba ìkòkò òhun padà. Àti ọba, ìjòyè pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìlú ni wón dá si i, tí wọ́n sì ń bẹ̀ẹ́ nítorí kí wón tó le yọ ìkókó yí, wọ́n ní láti gé igi obì yí kúrò. Ọkùnrin yí fárí gá, wọ́n sì gé igi obì náà.

Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe mọ̀ wípé àkísà tí yóò lọ sí ìsàlẹ̀ àkìtàn, bí ènìyàn bá fi igba abẹ́rẹ́ rán-an, kò ní gbọ́

Ìbànújẹ́ bá ọ̀rẹ́ tó gbin igi obì, ó sì dá ìkòkò náà padà ó sì gbà á. Ọmọbìnrin tí wọ́n fi idẹ sí lọ́run tí dàgbà láti wọ ilé ọkọ. Nígbà tí ìgbéyàwó ku ọ̀la, ọ̀rẹ́ tí wọ́n gé igi obì rẹ̀ wípé òun fẹ́ gba idẹ òun náà. Wọ́n ní láti bẹ́ orí ọmọbìnrin náà kí wón tó le mú idẹ yí jáde. Wọ́n sì bé orí obìnrin náà láti dá idẹ padà fún ọ̀rẹ́ tí wọ́n gé igi obì rẹ̀.

Ìtùmò ÌDÓRÓ GBA ÌKÒKÒ NI ÌDÓRÓ GBA IDẸ  ORÓ TÓ DÁ MI, NI MO DÁ Ọ, OGBÈ ṢE ỌWỌ́NRÍN, Ọ̀WỌ́NRÍN ṢE OGBÈ; ORÓ À KÓ DÁ KÒ DÀ BÍ À DÁ GBẸ̀YÌN. 


Òwe yí kó wa kí á má gbẹ̀san ohunkóhun tàbí ṣe ìlara torí àkódá oró kò dà bí à dá gbẹ̀yìn.
Ìdóró gba ìkòkò ni Ìdóró gba idẹ, oró tó dá mi, ni mo dá ọ, ogbè ṣe ọwọ́nrín, ọ̀wọ́nrín ṣe ogbè; oró à kó dá kò dà bí à dá gbẹ̀yìn.

Ẹ ṣeun nítorí àtìlẹ́yìn gbogbo ìgbà fún èdè ilẹ̀ Yorùbá àti ìgbé lárugẹ tó gbọ̀n-n-gbọ́n.

#YorùbáDùnlÉdè

0 comments:

Post a Comment

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA