Ọjọ́ ti lọ lórí bàbá yìí kí ó tó bí ọmọ látàrí ìdádúró tóní ṣùgbọ́n nígbà tí ó bí ọmọ, ọkùnrin pọ̀ nínú wọn.
Àjàlá ni ọmọ àbí gbẹ̀yìn bẹ́ẹ̀ni jàgídí jàgan ọmọ yìí pọ̀. Bàbá arúgbó yìí kú àti àwọn Ìyàwó rẹ̀ nígbà t'óyá.
Àwọn ẹ̀gbọ́n Àjàlá lósì ń mójú tó Àjàlá lẹ́yìn ìsípò padà àwọn òbí wọn ṣùgbọ́n Àjàlá kì í ràn wọ́n lọ́wọ́ rárá, gbogbo ará abúlé ló sì ń ní lára lórí ìwà rẹ̀.
Ó lọ fa ìjàngbọ̀n lọ́jọ́ kan, èyí pin àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ lẹ́mìí wọn sì sọ fún gbogbo ará abúlé láti fi ìyà tó bá yẹ jẹ́ ní ọjọ́ míì.
Ẹ̀ wẹ̀, Àjàlá kò mọ̀ pé ọjọ́ ìyà òun ti fẹ́rẹ̀ pé. Ó tún na ọmọ ìyá arúgbó kan níbi tí ọ̀rọ̀ yìí tí ń ta sí àwọn ará abúlé létí nígbà tí Ìyá arúgbó yìí lọ ń f'ẹjọ́ sùn ni wọ́n ti dáwọ́jọ-nàá látàrí àṣẹ tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún wọ́n.
Nígbà tí Àjàlá jàjà bọ́ lọ́wọ́ wọn, ó sunkún lọ sí ilé. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ béèrè pé, Àjàlá ta ni ó nà ọ̀?
Àjàlá dáhùn pé, ẹ̀yin náà kọ́ un.
Bí òwe yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn - Àjàlá ta ń nà ọ́, ẹ̀yin náà kọ́ un.
Ẹkú etí gbọ̀ọ́ àti ojú lọ́nà Ìtán d'òwe - A-rígbàjá òkò, Ìyàwó ń jà l'ọ́jà, orogún rẹ̀ ń dí'gbá nílé.
Àkójọpọ̀ rẹ̀ láti owó -
Ayanwuyi, Israel Temitope
Pẹ̀lú AIF MEDIA TEAM
0 comments:
Post a Comment