Láti ọwọ́ Israel Ayanwuyi
Bí a kò bá r'ẹ́ni fẹ̀yìntì bí ọ̀lẹ làárí.
Ìyá tí mo jẹ ní Ìwó kọjá àfi ẹnu sọ. Ìròyìn kò tó àmójúbà; ti àsọrégèé kọ́, kì í ṣe tẹnu lásán; díẹ̀ ni mo le rò nínú àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ mọ́nigbàgbé tó sẹ̀ ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn.
Ọjọ́ tí ebi bá ń pa ọ̀nà, kí á má rìn lọ́jọ́ náà ni ìwúre tí kóówá máa ń ṣe; ibi ilẹ̀ gbé ń pò ń gbẹ ẹ̀jẹ̀, kí á má rìn dé ibẹ̀ ni kókó ìwúre ọmọ ẹlòmíràn l'ówùrọ̀ bí wọ́n bá ń ṣe ń jí lórí ìbùsùn; bí ẹlòmíràn bá sì rí ìran ìdààmú ṣáájú ọjọ́, wọ́n a fìdí mọ́lẹ́ bí ẹni àárẹ̀ ń ṣe, bẹ́ẹ̀ akáwọ́gbẹ́kùn wọn tó ńwòran kì í ṣe ọ̀lẹ, inú ni wọn ń rò.
Kò sí ẹni tí í gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ tí dunnú, kò sí ẹ̀dá tó le gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ìyà rẹ̀ tó le wò sùn-ùn kó dá músò, kí Ẹlẹ́dàá má jẹ kí ohun tí ń dùn nínú wa kó di ìbànújẹ́, kí á má di arìndìn tí kò l'ọ́gbọ́n lórí lójijì.
Ǹjẹ́ ẹ jẹ́ mọ̀ pé láti ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni mo ti ma ń pariwo pé ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ láyé gbà; alágẹmọ tí ń yọ́ rìn, ikú ń pá, áńbèlèntè ọ̀pọ̀lọ́ tí ń jan ara rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ẹni tó bá gbọ́n ọgbọ́n kọ́gbọ́n, ìyà kí yà ló máa ń jẹ irú wọn.
Ení-ín làáse kátó ṣe èjì.
Ṣáájú ọjọ́ tí mo ń wí yí ni mo ti gba lẹ́tà kan tí mo tí ń retí láti ilé ìwé gíga tí mò ń wá ìtẹ́wọ́gbà sí fún ẹ̀kọ́-lọ-síwájú-síi. Ìrètí pípẹ́ a mọ́ ọn ṣe ọkàn láàárẹ̀, èmi tí ń mú ọkàn kúrò lórí rẹ̀. Mo ti ń gba ká mú pé ó tún di ọdún tí ń bọ̀ kí n tó gbìyànjú ilé-ẹ̀kọ́ yí lẹ́ẹ̀kan síi, àmọ́ lójijì ni mo rí ìwé gbà láti positi-ọ́ọ́físì pé wọ́n ti ní kí n wá bẹ̀rẹ̀ ì kẹ́kọ̀ọ́ ní wàrà-ń-ṣe-sà ní bẹ̀.
Bí iṣẹ́ kò bá pé ni, ẹnìkan kì í pé iṣẹ́. Mo mú oókan, mo fẹ́ fi kún èjì, kí n gba oko aláwò lọ.
À tí àkùkọ ọjọ́ kejì ni mo ti jí. Bí ó ti di àfẹ̀mọ́jú, ní jẹ́jẹ́, ní pẹ̀lẹ́-kùsù, láì fi ohun kan bọ ẹnu, ni mo kùrò nílé—ní jẹ́nẹ́sísì ọjọ́ àbámẹ́ta náà. Ọ̀gangan ọ̀nà ni aláké ń sọ, mo gbéra mò ń wá takisí tí ó le gbé mi lọ ibùgbé àǹtí mi tó wà ní Ilé-márùn-ún nílùú Ìwó. Apá lará èjìká ni ìyekan, mo nílò láti lọ bèrè ìrànwọ́ nípa ti owó fún ìrìn-àjò lọ sí ilé-ìwé náà,tó wà Ìbàdàn.
Mo kọ́kọ́ ṣe ìfòró fún wàkàtí kan lé ìṣẹ́jú mẹ́wàá kí n tó rí takisí tí ò ní èrò, tó le gbé èmi nìkan lọ ibi mò ń rè. Nígbà tí mo rí mọ́tò, inú mí dùn, ìrònú àìjẹun tó ti wà lọ́kàn mi tẹ́lẹ̀ sá kúrò ráúráú.
Ní ìwọ̀nba, ọkàn mi balẹ̀ bí a ṣe ń lọ. A kò dúró, à ń tẹ̀ síwájú.
Bí ènìyàn yó bá jẹ ìyà ní Ìwó, kó wà ní Kàdúná, ó di dandan kó wálé.
Èmi kò mọ!
Ẹgbẹ̀rún kan alápapọ̀ ló wà lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n ìgbàgbé ṣe mí láti bèrè lọ́wọ́ bàbá òní-takisí yí bí wọ́n bá ní séńgì. Ọkàn mi kò tilẹ̀ sí síbẹ̀ rárá. Ìrònú kí n de ibi mò ń lọ, kí n báwọn sọ ohun mo ní wí, kí owó kó jáde ni gbogbo àfiyèsí mi. N kò tilẹ̀ gbìyànjú láti béèrè, mo ń gbàdúrà kí Bàbá yí ní séńgì ṣùgbọ́n mo tún ni lọ́kàn pé bí wọn ò bá ní, a ó jọ dà á rú fún ara wa ni láì mọ̀ pé èmi gan-an ni yóò fara-kásá.
Bí a ṣe ń lọ ni Bàbá ònímọ́tò yí gbé ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ wọn lé mi lọ́wọ́, wọ́n ni kí n bá wọn tẹ àtẹ̀jísẹ́ kan ránsẹ́ sí ọmọ wọn àkọ́bí lọ́kùnrin.
Ní kété tí mo bá wọn ṣe èyí tán, mo mú ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ títí tí mo fi sọ. Èmi ti gbàgbé, Bàbá náà kò rántí béèrè mọ́.
Gbàrà tí mo ni kí wọ́n já mi ni mo yọ owó lápò, ló bá di Ẹgbẹ̀rún kan owó náírà. Mo wo ojú Bàbá, Bàbá náà wo ojú mi, ojú wa ṣe mẹ́rin. A fi bí ìgbà tí èèyàn bá ń wo sinimá. Bàbá ònímọ́tò yarí fún mi lórí séńgì Ẹgbẹ̀rún kan owó náírà tí wọn kò ní, wọ́n ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò ní ilé ni. Wọ́n ní kín n rìnsó ká lọ wáa fọ́ sí wẹ́wẹ́ ní àyíká wa.
Kí Ọlọ́run májẹ kí á rí ogun adánidúró lóòrọ̀kùtù ni kìkì ọ̀rọ̀ tí Bàbá yí rán mọ́nu.
A ti gbìyànjú díẹ̀, ṣùgbọ́n kò jásí ohun kan. Àyíká kò tilẹ̀ tíì kún nítorí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ni. Ìfòró pọ̀.
Nígbà tó yá, mo tọrọ gááfárà láti ṣe ẹ̀yọ́ láàrín ìṣẹ́jú kan. Mo fún Bàbá l'ówó kí wọ́n dúró dè mí, mo wọ kọ̀rọ̀-kọ́ńdú kan lọ.
Mo ṣe díẹ̀ níbẹ̀ nítorí ìfòró náà tún jí ti ebi tó ń pamí tẹ́lẹ̀. Bí mo ṣe ṣetán, tí mo jáde, mo wá Bàbá ònímọ́tò tì. Eré ni mo pèé, ó di òtítọ́ mọ́ mi lọ́wọ́.
"Èèmọ̀ rè o!" Mo pariwo. Àfi bí ìgbà tí èèyàn bá ń lálàá.
Ìbánújẹ́ mu mí lómi, ara mí tutù wọ̀!
Gbogbo àgbọ́kànlé mi náà ni owó yìí, ìrètí tí mo tún ní ni bí mo bá de ibi mò ńlọ láti gbà síi fún ìrìn-àjò pọndandan tí mo fẹ́ lọ.
Ìdóró gba ìkòkò ni ìdóró gba idẹ.
Orí ìnàrò náà ni mo wà tí mo fi rántí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ Bàbá yí tí ń bẹ lápò mi.
"Mo rántí. Mo ti rántí!" Lorin tuntun tí mo mú banu. Mo tilẹ̀ gbàgbé pé òpópónà ni mo wà.
Oró àkọ́dá kò le dàbí àdágbẹ̀yìn, mo ṣe bí ọwọ́ mi ti mókè.
Bí a bá ń wá owó lọ, tí a sì rìn pàdé iyì lọ́nà, ó yẹ ká padà lọ ilé dàìrẹ́tì ni.Kódà, mo dá-wọ̀ọ́-ìdùnnú pé owó de, bí mo bá le rí ẹni ra ẹ̀rọ yí, n kò nílò láti wojú àǹtí mi fún ìrànwọ́ owó kankan mọ́ lórí ìrìn-àjò náà. Bí a bá ní eégún baba ẹni yóò jó, bí a bá ní kò sì ní jó mọ́, kò sí bàbá-ńlá ẹni tí í mú ni síi. N ò gbìyànjú láti pe ẹni tí ó súnmọ́ Bàbá yí rárá. Ní ṣe ni mo lu ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà pa.
Ohun tó ṣeé faga, là ńfaga sí; èwo ní, Ìwòyí àná mo ti na àna mi fága-fàga?
Èmi alára gan kò ní ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n n ò bèsùbẹ̀gbà, mo fònà títì iwájú mi—N ò wulẹ̀ tẹ̀ síwájú láti dé ilé àwọn àǹtí mi mọ́ lọ́jọ́ yí. N ò ronú pé mo ti dé òpópónà ilé wọn, mo mórí padà, ọpọlọ mi bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ bí ago, ọ̀nà à ti ta ẹ̀rọ yí ni mo ń sánnà.
Ṣe bí wọ́n ní kí á dàálẹ̀, ká tún sà kì í ṣe fáàrí tí ònígaàrí le se ni. Ọ̀rọ̀ tèmi kò gba bẹ́ẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ibùsọ̀ mẹ́wàá mìíràn. Mò ń wá ẹni tí ó le ra ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ náà.
Kí Èdùmàrè má jẹ́kí á sọnù kí á tó sọnú.
Gbogbo àsìkò yí, ebi tún ti sá kúrò. Mo tẹ̀ ṣíwájú ìrìn mi lọ sí ibi kan tí mò tí ma ń gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n ti máa ń ra àti tà ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ àlòkù.
Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ibi tí mò ń lọ tí òjò fi sú, bí-eré-bí-eré, ọwọ́ òjò náà bo lẹ̀. Èmi tilẹ̀ ń ṣe eré àwọn ọmọdé, mo ní "Òjò mọ́ lọ, atẹ́gùn mọ́ ọn fẹ́"
Omi kín-ń-kín làá r'ẹ́lá sí, òjò bẹ̀rẹ̀, mo sá fún òjò kí n mọ́ tún jẹ ìyà míì lọ́wọ́ òjò àti láti dáàbò bo ẹ̀rọ náà.
Òjò náà rọ̀, ó fẹ́rẹ̀ wú òkú ọ̀lẹ.
Mo dúró-dúró, àfi ìgbà tí òjò náà dáwọ́ tán pátápátá. Mo tẹ̀ síwájú, mo pàpà dé ibẹ̀. Olè ní mọ ẹsẹ̀ olé tọ̀ lórí àpáta, èmi ò tilẹ̀ mọ pé ó ní èdè ìbánisọ̀rọ̀ kan tó wà láàrin àwọn ènìyàn tó ń ta ohun kan fún ara wọn níbẹ̀.
N ò tí sọ̀rọ̀ púpọ̀, mo kàn fi ọjà hàn wọ́n lásán ni, a ò tíì bẹ̀rẹ̀ ìdúnàá-dúrà tí wọn fi dá mi mọ̀ pé èmi kì í ṣe ara wọn.
Ọgbọ́n ju ọgbọ́n lọ, ọ̀gá wà lóòótọ́.
Ọ̀kan nínú wọn gba ẹ̀rọ yí, ó ní òun ń bọ̀ wá, òun kàn fẹ́ fi han ẹniti owó ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Láàrin ìṣẹ́jú béléńjà, n kò rí ẹni yí mọ. Mo dúró ṣáà, ń kò gbúro ẹnìkan.
Lẹ́yìn wákàtí kan, mo béèrè arákùnrin náà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tó kù tí wọn ń bá iṣẹ́ tiwọn lọ, wọn ní kí n dúró. Bí wọ́n ṣe fi ọgbọ́n àrékérékè yí tàn mí tó fi di agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́ nìyí.
Mo wá pinnu láti ṣe bí ọkùnrin, mo yarí fún wọn. Ṣùgbọ́n kí n tó wí kí n tó fọ̀, ìgbájú ìgbámú ni wọ́n fi dá mi lóhùn, wọ́n ní ṣe àwọn ni àwọn gba ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ yí lọ́wọ́ mi ni, kín n má wá ẹni náà lọ.
N ò kúkú le dá wọn mú, agídí ọkàn-àyà mi pẹ̀lú wọn ló tún kó ìyà jẹ mi púpọ̀. A jọ ń fà á pé ṣe bí ara wọn ni ẹni náà. Àwọn kò tilẹ̀ fi ọ̀rọ̀ dá mi lóhùn mọ́ nígbà tí wọ́n ti rí pé n ò ní gbọ́, ìyà ni àwọn mẹ́ta náà fi dá mi lóhùn, wọn tún pè mí ní olè.
Kódà, ilé mi kọ́ ni mo sùn lọ́jọ́ náà. Iwájú kò sé lọ, ẹ̀yìn kò sé padà sí, ìta ni mo sùn. À ṣé ìlàkàkà mi lórí asán, ọwọ́ àwọn ọ̀daràn míràn ni mo lọ kó sí.
Ọ̀kánjúà, olè, ọ̀lẹ àti àìhùwà-bí-ọlọ́run jẹ́kí n pàdánù ọdún kan fún Ẹ̀kọ́ mi, ó mú mi jẹ ìyà bí ọ̀daràn, ó mú mi sùn ní ìta láìṣe ọdẹ, ó mú mi kọ́gbọ́n lọ́nà tí kò rọrùn àti ọ̀nà ìtìjú. Ẹkún àti ìpayínkeke ní ọ̀gànjọ́ òru ọjọ́ pọ̀, tí mo si fẹ́ẹ̀ le fi ọjọ́ tí abími bú. Gbogbo ẹ̀, àfi ọwọ́ fà mi náà ni. Kò sí àwíjàre kan fún oníwà-kíwà.
Kí Olódùmarè ràn wá lọ́wọ́ ni gbogbo ìgbà, ká má fi ọwọ́ ara wa ṣe ara wa. (Àṣẹ).
Ṣíṣe Ìgbéga Àwọn Ogún Dáradára Yorùbá Ló Jẹ Wá Lógún
AIFMEDIA || YÒRÙBÁDÙNL'ÉDÈ
© Copyright, Israel Ayanwuyi, 2020