EWÌ ALOHÙN: ÌJÁLÁ ÀTI ÌRÈMỌ̀JÉ BY ISRAEL AYANWUYI


EWÌ ALOHÙN: ÌJÁLÁ ÀTI ÌRÈMỌ̀JÉ
Láti ọwọ́ Israel Ayanwuyi 

Lítíréṣọ̀ Alohùn jẹ́ akójọpọ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀, òye, ohùn ẹnu àti ìrírí àwọn Bàbá ńlá wa tí a fi ohùn dídùn gbé jáde. Ópín sí ọ̀nà méjì: a. Ajẹmẹ́sìn Àbáláyé, àti; b. Ajẹmáyẹyẹ.

Lára àwọn Ajẹmẹ́sìn Àbáláyé ni ẹsẹ̀ ifá, Èṣù pípè, Ọya pípè, Àrúngbé abbl.
Àwọn Lítíréṣọ̀ Ajẹmáyẹyẹ ni Ẹkún Ìyàwó, Etíyẹrí, Dadakúàdà, Rárà, Ìjálá, Bírípo, Òlélé abbl. 


Láti ìgbà ìwáṣẹ̀ láti ní àwọn (ewì) orin àtẹnudẹ́nu káàkiri ilẹ̀ "káàrọ̀-ẹ-ọ̀-jíire bí?", ọkàn pàtàkì sì ni Ìjàlà àti Ìrèmọ̀jé jẹ́. 

Ìyàtọ̀ ṣókí tó wà láàrin àwọn ewì alohùn—Ìjálá àti Ìrèmọ̀jé—ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn àti ìwúlò Ìjálá ni àfojúsùn àpilẹ̀kọ yìí. Bótilẹ̀jẹ́wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀, tí àwọn mìíràn sì mọ̀ ṣùgbọ́n wọ̀n kò gbà, òtítọ́ ọ̀rọ̀ ni pé ohun tí à ń pè ní Ìjàlá lónìí kì í jẹ́ Ìjálá tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀ nígbà ìwáṣẹ̀—'Ìrèmọ̀dó' tàbí 'Ìrèmọ̀jé' ni wọn máa ń pèé nígbà náà.

Ìtumọ̀ Ìrèmọ̀jé ní gúnmọ̀ ni "Kíki Ògún". Ọ̀kan gbòógì ni Ìrèmọ̀jé jẹ́ nínú àwọn ewì alohùn (orin àtẹnudẹ́nu) Ilẹ̀ Yorùbá. Bí a bá fẹ́ sọ, a le wípé lágbájá tàbí tàmẹ̀dù (Èèyàn kan) ń sun Ìrèmọ̀jé/Ìrèmọ̀dó tàbí kọ orin Ìrèmọ̀jé/Ìrèmọ̀dó. 

Igi kì í dá lóko kó pa ará ilé. Bí ìtàn ṣe fi yé wa, ó ní ohun kan tó pín Ìrèmọ̀dó àti Ìjálá sí méjì. 

Ohun tí ó sọ Ìrèmọ̀jé di Ìjàlá nígbà náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìwádìí, ni pé, láyé àtijọ́, bí àwọn ọlọ́dẹ bá pàdé ará wọn lóde akẹgbẹ́ wọn, tí ó bá wá di òní aré àti ẹ̀fẹ̀, wọ́n le bẹ̀rẹ̀ sí ń ta kàn-ǹ-gbọ̀n orin Ìrèmọ̀jé sísun láàrin ara wọn. A fi bí pé wọn ń jiyàn pé o le pa mí láyò, o ò le pa mí láyò, tí ẹnì-kín-ní-ín bá ri wípé ẹnì-kejì fẹ́ borí òun—kàkà kéku ó jẹ ṣèṣé, a ó fi s'àwàdà nu ni—ni irú ẹnì-kín-ní-ín náà yóò wá pinnu láti fi agbára ségun ẹnì-kejì nípa yínyín ataare sí kọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ohun míràn. Ẹni náà yó sì ma pọfọ̀ àbí pògèdè títí débi pé enì-kejì tí wọ́n ń dìjọ ń figagbága yò máa pọ ẹ̀jẹ̀ lẹ́nu tàbí rélulẹ̀ gbàà. 

Bí àwọn ènìyàn bá ti ń lọ wòran, èyí ṣe okùnfà ìbéèrè tí wọn máa ń bi ara wọn pé, "Ní bo lẹ̀ ń lọ?" Tí àwọn òǹwòran yóò fún wọn ní ìdáhùn pé, "Àwọn ń lọ ń wòran orin Ìrèmọ̀jé, ní ibi tí wọ́n tí ń ṣeré "Ìjà Ńlá".

Eré "Ìjà Ńlá" nígbà náà ni à ń pè ní ÌJÀLÁ lónìí nípasẹ̀ òfin tó rọ̀ mọ́ ṣíṣe ìsúnkì àti ìpàrójẹ gbólóhùn nínú gírámà èdè Yorùbá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ni kò sí "ÌJÀ ŃLÁ" mọ́, ÌJÀLÁ ni orúkọ tí gbogbo ayé mọ̀ sì í.
 


Àwọn àṣàyàn orin tí Ògún ma ń kọ nígbà ayé rẹ ni ÌRÈMỌ̀JÉ tí ó wá di eré ÌJÀLÁ jákèjádò ilẹ̀ "káàrọ̀-ẹ-ọ̀-jíire bí?".

Ògún ló ní Ìrèmọ̀jé. Nígbà míràn, wọn a máa sọ pé Ìrèmọ̀jé-Ògún. 

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tún kò ṣe papọ̀ mọ́ òsì, tí òkú kò jọ ìyàwó, Ìrèmọ̀jẹ́/Ìrèmọ̀dó àti Ìjàlà kàn jọ ara wọn ni, wọn kì í ṣe ọ̀kan náà. Ìjàlà ló wà fún onírúurú ayẹyẹ, ṣùgbọ́n orin orò ìsípà ọdẹ ni Ìrèmọ̀dó fún ọdẹ ẹgbẹ́ wọn tó bá rèwàlẹ̀-àṣà. Èyí fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé Ìrèmọ̀jé kì í ṣe orin ẹ̀fẹ̀, àríyá tàbí orin lásán yàtọ̀ sí bí a ṣe le sun Ìjàlà ní ìgbàkúgbà. Àwọn míràn a máa pe Ìrèmọ̀jé ní orin òru. 

Bí ọmọdé kò bátàn, yò bá àróbá. Nígbà ayé Ògún gẹ́gẹ́ bí ìtàn àrọ́bá ṣe fi yé wa, tí Ògún bá ń múra láti lọ igbó-ọdẹ, orin Ìrèmọ̀jé yìí ló máa ń sun fún àwọn ọmọdé. Yóò máa kì wọ́n lọkọ́ọ̀-kan àti èjèèjì ní mẹsan-mẹ́wàá. Ìgbà míràn ẹ̀wẹ̀, tí Ògún bá wá lọ sóde àríyá, ó maa ń sun Ìrèmọ̀jé yìí láti fi dá àwọn ènìyàn lára yá. Ìgbàkúùgbà ni Ògún ti ó dá ÌRÈMỌ̀JÉ tí ó di ÌJÀLÁ sílẹ̀ ma ń kọ orin náà.

Ìgbà míràn, Ògún a máa kọ́ ní bi ìkómọjáde, ibi òkú àgbà àti ayẹyẹ ìgbéyàwó, àti pẹ̀lú níbi àjọ̀dún Ògún àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ. Ní irú àsìkò àjọyọ̀ yí, Ògún àti àwọn ènìyàn yóò pè ṣè oúnjẹ àti ọtí fún tolórí tẹlẹ́mù. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Ògún ni àyípadà orúkọ dé bá ÌRÈMỌ̀JÉ tí ó di ÌJÀLÁ tí gbogbo ọmọ ọdẹ àti àwọn míràn tí ó fẹ́ràn rẹ le sun. 


Ní òde òní, Ìjàlá sísun ti tàn káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, ó ti pẹ̀lú di ohun tí ogúnlọ́gọ̀ ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹwà èdè Yorùbá ń lọ́wọ́ gbọ́ àti sun ní ibi ayẹyẹ ọ̀jọọ̀jọ̀kan bí àpẹẹrẹ: Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí, Ìsílé, Ayẹyẹ Ìgbòmìnira àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà àwọn ẹlẹ́sìn Ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ń pe àwọn Oníìjálá ní ọ̀nà ti Jésù sí òde ti wọn.

Ní àkótán, ìjàlá lónìí wúlò fún oríṣiríṣi ohun ní ṣíṣe pàápàá jù lọ, láti máa gbé ògo àṣà, ẹwà èdè àti ìṣe ìran Yorùbá sókè, ó ti di ohun Ìkéde lórí Ẹ̀rọ Rédíò, Ẹ̀rọ Amóhùnmáwòrán, kíki oríkì orílẹ̀, ìlú tàbí tí ènìyàn, tí èyí sì fún ogunlọ́gọ̀ ènìyàn láti mọ ara wọn délé-délé nínú oríkì orílẹ̀, ti ìdílé, tí ara wọn, àti ti àwọn ìlú ìṣẹ̀ǹbáyé ní èdè Yorùbá. 


ÈÈWỌ̀ ÀTỌWỌ́DÁ TÓ RỌ̀ MỌ́ ORIN ÌJÀLÁ KÍKỌ TÀBÍ SÍSUN 
A. Ọdẹ kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó ọdẹ ẹgbẹ́ rẹ̀. 
B. Bí ọdẹ bá wọ ilé ọdẹ ẹgbẹ́ rẹ, tí ó bá dìde fún-un, kò gbọdọ̀ jókòó níbẹ̀ rárá. Àmọ́ ọkọ rẹ̀ le dìde bọ́ sórí àga tí ìyàwó rẹ̀ fi jókòó. Àlejò yóò si padà jókòó ní àyè tí ọkọ ti dìde kúrò. 
D. Bí ọdẹ bá pàdé ìyàwó ọdẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ míràn lójú ọ̀nà oko tí kò rí èèyàn gbé ẹrù rùú, tí irú ọdẹ bẹ́ẹ̀ bá gbé rùú. Irú ọdẹ bẹ́ẹ̀ yóò já AJẸ̀ lé e lọ́wọ́ pé kí ó fún ọkọ rẹ̀ tí ó bá délé. Ó sì le fún un ní àháyá ìbọn pé kí ó fún ọkọ rẹ̀ nílé.
 
ÌKÌLỌ̀: Ikú ni ó má ń gbẹ̀yìn irúfẹ́ ọdẹ tí ó bá fi ojú ré nà àwọn èèwọ̀ wọ̀nyí. 


Ìjàlá wúlò púpọ̀ nínú ìran Yorùbá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fí ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ ò jọ́ wọn. 


DÍẸ̀ LÁRA ÀWỌN ÌWÚLÒ ÌJÀLÁ LÁWÙJỌ ÌRAN YORÙBÁ 
A. Ó má ń mú ìwúrí wá. 
B. Ó mà ń jẹ́ kí ohun kan yé ènìyàn yékéyéké 
D. A má ń fi ń bá olè wí láwùjọ tàbí àwọn ìwà ìbàjẹ́ míràn. 
E. A le fi gbà ènìyàn, ìjọba, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní àmọ̀ràn tàbí ìyànjú.
Ẹ́. Àwọn mìíràn fi ń ṣe iṣẹ́, fi bọ́ ara wọn àti ìdílé wọn pẹ̀lú. 


Ṣíṣe ìtọ́jú àwọn ogún daradara wa jẹ iṣẹ́ wa 
AIFMEDIA || YÒRÙBÁDÙNL'ÉDÈ
© Copyright, Israel Ayanwuyi, 2016
01032016

0 comments:

Post a Comment

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA