Ìtàndòwe - Ẹnití kò le se bí aláàárù l'Óyìngbò, kò le se bí Adégbọrọ̀ l'Ọ́jà ọba
Adégbọrọ̀ fi ìlú Ìbàdàn sílẹ̀, ó kọ rí sí ìlú Èkó láti lọ ṣe iṣẹ́ alábàárù ní agbègbè kan tí wọ́n ń pè ní ÒYÌNGBÒ. Ń gbé ẹrù sórí, ń ṣe alábàárù níbẹ̀. Nígbà tí Adégbọrọ̀ ṣe iṣẹ́ yí fún gbà pípẹ́ láì ṣe ìmẹ́lẹ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ o ń fi owó pamọ́, bẹ́ẹ̀ ló bá ra ọmọlanke láti máa fi gbé ẹrù dípò rírù sórí.
Eléyìí jẹ́kí ìrọ̀rùn bá iṣẹ́ alábàárù rẹ̀ tó ń ṣe. Nígbà tó wá tún fi ọmọlanke ṣe iṣẹ́ kárakára díẹ̀ si, ó tún wá ra ọmọlanke tó pọ̀ láti fi máa rẹńtì fún àwọn ènìyàn lọ́rísìrísìí fún iṣẹ́ alábàárù láti rọrùn.
Nígbà tí ó tún túnbọ̀ ti ọmọlanke fún ọdún mẹ́jọ gbáko pẹ̀lú gbogbo owó tó ń pá wọlé lórí àwọn ọmọlanke tí ń yá àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló bá kó owó jọ tó sì di ẹnití ó ra mọ́tò. Mọ́tò tó rà jẹ́ èyí tí a mọ̀ sí bọ́lẹ̀kájà, ó kọ́ bí wọn ṣe ń wa ọkọ̀ láti mó jú tó ọkọ̀ náà fún ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ń wa ọkọ̀ bọ́lẹ̀kájà náà tó fi pé ọdún mẹ́rin.
Ní Ọlọ́run bá gbọ́ àdúrà Adégbọrọ̀, ló bá ra mọ́tò mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a mọ̀ sí bọ́lẹ̀kájá tó sì ń gbé fún àwọn ènìyàn láti m'ówó wọlé.
Ó tó àsìkò tí Adégbọrọ̀ yó kọ́ ilé, ó wá korí sí ìlú Ìbàdàn ní agbègbè tí wọn ń pè ní ọjà-ọba, ìbẹ̀ ló lọ kólé sí. Adégbọrọ̀ kọ́ ilé àrà-mọ̀-ǹdà yí tán, àwọn ènìyàn tó mọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá ń ríi, wọ́n ń béèrè pé ọ̀nà wo ló gbé gbà tí ó ṣe ń dùn tó ṣe ń dá fún-un, Adégbọrọ̀ wá ń bi wọ́n léèrè pé ṣe wọn lé gbé ẹrù sórí, ṣe wọn lé ṣe alábàárù ní-bi-kí-bi, ṣùgbọ́n wọ́n á dáhùn pé láéláé àwọn kò le se bẹ́ẹ̀.
Ibẹ̀ ni Adégbọrọ̀ ti ń fún wọn lésì pé, "Èèyàn tí kò le se bí Alábàárù l'Óyìngbò, kò mà le se bí Adégbọrọ̀ l'Ọ́jà ọba". Láti ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ inú ìtàn yí ti di òwe nílẹ̀ Yorùbá.
Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, iṣẹ́ wo ni ìwọ ń ṣe tí o kò tẹpá mọ́? O kò kàwé tàbí tẹpá mọ́ iṣẹ́ kí ṣe tó wù ọ́ láti yàn làáyò, ò ń sọ pé orílẹ̀-èdè ibìkan kò dára. Fí eléyìí kọ́gbọ́n àti ìpinnu ayé tiẹ̀, èèyàn tí kò le se bí aláàárù l'Óyìngbò ni, kò le se bí Adégbọrọ̀ l'Ọ́jà ọba. Tí o bá fi irun dúdú ṣe iṣẹ́, kí o mọ́ bà fi irun funfun gba àárù ni.
Ẹnití kò le ṣe bí aláàárù l'Óyìngbò, kò le se bí Adégbọrọ̀ loja ọba. Don't stay idle because an idle man is a devil's workshop.
We bring you virtues and godly heritages from Yorùbá culture, tradition and lifestyle. #YorùbáDùnlÉdè
Source - https://bit.ly/2TbBvmS
#YorùbáDùnlÉdè #YorubaHeritages #AIFMEDIA
© Israel Ayanwuyi, 2020
0 comments:
Post a Comment