ÌTÀN: ÌBÀNÚJẸ́ ỌJỌ́ KAN



ÌTÀN: ÌBÀNÚJẸ́ ỌJỌ́ KAN
Láti ọwọ́ Israel Ayanwuyi 

Lọ́gán tí mo rí ìmọ́lẹ́ ọjọ́ ajé, mo gbéra nílẹ̀, mo kí Olódùmarè kú òwúrọ̀ nítorí pé Òun náà ni Ọba àjìkí, Òun tún ni Ọba àjígẹ̀. Kò pẹ̀ẹ́ kò jìnnà ni mo gbọ́ tí Bàbá lókè ń dá mi lóhùn pé, "A ò jíire bí?"

Nígbà tí Òrìṣà-Òkè ti dáhùn, mo tẹ̀síwájú láti kí ará ilé mi lápapọ̀. A dúpẹ́ tí Èlédùmarè jí wa lọ́kọ̀ọ̀kan, tí a ò ti ojú orun bọ́ sí ojú ikú, àlákálàá náà kò sẹ̀rù bà wá lójú ìran. 

Èmi wọ balùwẹ̀ léṣẹ̀ kan náà, mo múra, mo gbé gbogbo ẹrù mi láti máa lọ ìdí-kọ̀. Gbogbo ará ilé bá ń fi igbe ìpàrọwà ta fún mi láti mọ ọmọ ẹni tí mò-ń-ṣe. Wọn kò fẹ́ kí nlọ, kódà wọ́n banújẹ́ láti wí fún mi pé ó dìgbà ó ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe mọ: Bí ará ilé ẹni kò bá ṣ'ènìyàn rárá, a ò le fi wé aláròó lásán. 

Mo wà nílé fún ọjọ́ mẹ́fà tó parí oṣù tó gbẹ̀yìn ọdún àti ọjọ́ mẹ́jì àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ọdún titun tó tẹ̀lé. Àjọyọ̀ ìparí àti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ní ṣókí ni mo wá bá wọn ṣe nígbà tí wọ́n kúkú fún mi ní họlidé ọjọ́ mélòó kan ni ibi iṣẹ́. 

Ó pọndandan fún mi láti padà sí ẹnu iṣẹ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹẹ̀ta (èyí ni ọjọ́ kẹẹ̀ta oṣù kínni ọdún tí a tún mọ̀ sí oṣù Sẹẹrẹ) gẹ́gẹ́ bí òfin àti ìlànà ilé-iṣẹ́ tí mò ń bá ṣiṣẹ́, n ò le kọ̀ láti mọ́ lọ à fi bí mo bá ti rí iṣẹ́ sí ibòmíràn. 

Mo gùnlẹ̀ sí ìdí-kọ̀ àwọn ọlọ́kọ̀ èrò lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́wàá sáńgílíńtí, Elédùmarè ṣàánú mi, àwọn èrò kún sínú bọ́ọ̀sì náà lẹ́yìn wákàtí kan. (Èmi gbà pé wákàtí kan yí kò tí ì pọ̀ jù nítorí àgbègbè ibi tí mo ti wá: à ti rí èrò ìlú tí mò ń lọ kò rọrùn).

Ni a bá gbéra, a mórí lé ìlú Kaduna. Nígbà tí n ó fi dé ìlú ńlá, ilẹ̀ ọjọ́ yí ti sú pátápátá ní torí àìjára mọ́rín dírẹ́bà awakọ̀ yìí. Agogo mẹsan-àbọ̀-dín-ní-ìṣẹ́jú-mẹ́ta ni wọ́n já mi ní bọ́sí-sitọpù tó gbẹ́yìn.

Mo dá òní-kabúkabú dúró ní ọwọ́ iwájú. Ó gbé mi tòhun ti ẹrù, ó já mi níwájú ilé tí mò ń gbé gan-an.

Bí mo ṣe yanjú òní-kabúkabú tán ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí níí gbá gétì ilé tí mò ń gbé ṣùgbọ́n n ò gbọ́ ìjẹ́ ẹnìkan. 

N ò tilẹ̀ ní iná kankan lórí ẹ̀rọ-ìbánísọ̀rọ̀ mi kín n tó gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ yí gan-an, n ò le pe ẹnikẹ́ni láti inú ilé fún ìrànwọ́ pẹ̀lú ṣíṣí gétì. A rí wo àwọn tó tún tan ẹ̀rọ-amúnáwá nínú ọgbà gan-an kò le jẹ́kí ọkùnrin asọ́gbà gbọ́ ohùn tó wù kó jáde láti ọ̀dọ̀ tèmi ní ìta. 

Iná ò gbọ́dọ̀ kú, omi ò gbọ́dọ̀ jò dànù, ìrònú di méjì fún abomi s'ẹ́nu fẹ́ná mi.

N ò kọ́kọ́ gbàgbọ́ tàbí rò ó pé mo le sùn ní ìta. Pé mo tiẹ̀ gúnlẹ̀ láyọ̀, tí n ó sì le wọ iṣẹ́ padà ní òórọ̀ ọjọ́ kejì, ògo ni fún Adẹ́dàá. 

Gbogbo ìrònú mi wá tún ń lọ pé, ó ṣeéṣe kí wọn pa ẹ̀rọ-amúnáwá jẹnẹrétọ̀ náà láì pẹ́ ṣùgbọ́n wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ láàrin wákàtí-kan-lé ìṣẹ́jú díẹ̀ tí mo ti ń dúró. Mo wá ronú jinlẹ̀, mo wòye pé àtànmọ́jú gbáko ni wọ́n fẹ́ lo ẹ̀rọ-amúnáwá náà. 

Adágún odò tàbí àbàtà ni alákàn ń wẹ̀
Kò sí ṣíṣe kò sí àìṣe, mo tẹ́ aṣọ ìró kan nínú ẹrù mi sílẹ̀, mo sùn ní ẹ̀gbẹ́ kan gétì. Èyí jẹ́ ìgbà àkókò tí n ó sùn ní ìta gbangba. Bótilẹ̀jẹ́pé inú ìfòyà ńlá àti àfonífojì ni mo wà, gẹ́gẹ́ bí obìnrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewu ló tún wà nínú ìgbéṣẹ̀ mi yìí. N ò sì sùn wọra títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ kejì.

Ara ríro àti orí fífọ́ látàrí ìrìnàjò tí mo rìn gan kò tún jẹ́ kí n gbádùn. 
Ọjọ́ yìí gan ni mo mọyì àwọn tí ogun sí ní ipò padà, àwọn ọmọ aláìní ìyá àti bàbá, àwọn aláìní ilé lórí, àwọn tí ojú ń pọ̀n àti àwọn tí ẹbí tàbí ará ti kọ̀tì. Mo banújẹ́ púpọ̀, orí ló yọ mi tí n ò lùgbàdì ewu òru. 

Ìròyìn kò tó àmójúbà, ṣùgbọ́n bí ẹ bá rí ẹni ojú ń pọ́n, ẹ rànwọ́nlọ́wọ́, ẹ nawọ́ àlàáfíà àti ìtọ́jú tó wà ní ìkáwọ́ yín sí wọn. 

Èdùmàrè kòní sọ ẹnìkẹ́ni nínú wa tàbí nínú àwọn ènìyàn wa di aláìní. Ọlọ́run Olódùmarè yóò sì ṣàánú àwọn aláìní nínú ọrọ̀ Rẹ̀ kíkún àti ọlá ńlá. Àṣẹ.


Ṣíṣe Ìgbéga Ogún Dáradára Yorùbá Ló Jẹ Wá Lógún 
AIF MEDIA | YÒRÙBÁ DÙN LÉDÈ
01022019
© Copyright, Israel Ayanwuyi, 2019


0 comments:

Post a Comment

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA