Orúkọ Àwọn Ọba Pàtàkì Ilẹ̀ Yorùbá Nígbà Ìwáṣẹ̀


Orúkọ Àwọn Ọba Pàtàkì Ilẹ̀ Yorùbá Nígbà Ìwáṣẹ̀ 
Láti ọwọ́: Israel Ayanwuyi, 2013

Ní ilẹ kóòtù-ẹ-ò-jíire, àwọn ọba alayé ló má ń darí àtò ìlú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni wọ́n di ọba látàrí ipa pàtàkì tí wọ́n kó nínú ìdásílẹ̀ àgbègbè kan tàbí kí wọn jẹ akọni yálà nípa isẹ́ ogun jíjà, ọdẹ tàbí ọ̀nà mìíràn tí wọn bá yàn láàyò.

Títí di òní olónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ló ń dáfá láti mọ ẹni tí ó yẹ láti jọba, àwọn mìíràn tí lẹ̀ ti ní ìdílé kan tó ń jọba nílùú wọn.
Ṣùgbọ́n, kin-ní kan yé wa wípé orí tí yóò bá jẹ ọba, nínú agogo-idẹ ní tí wá; Ọrùn tí yóò bá lo èjìgbà-ìlẹ̀kẹ̀, inú agogo-idẹ ni yó ti wáyé.

Àwọn Ìpínlẹ̀ tí ati le rí àwọn ọba alayé Yorùbá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nì wọ̀nyí;
Oyo
Ogun
Ondo
Kwara
Kogi
Èkó.

Ipinle Èkó:
Ọba ti Èkó, Àyángúnrìn ti Ìkòròdú, Ọlọ́jà ti Ẹ̀pẹ́, Onísọlọ̀ ti Ìṣọlọ̀, Ọba Elégúsì ti Ègùsì, Agbókèjoyè ti Ìlògbó -Erémin, Akaran ti Badagry, Olú ti Mushin

Ìpínlẹ̀ Kwara:
Ẹmíà ti Ìlọrin, Ọlọ́fà ti Ọ̀fà, Olóròó ti Òróó, Olúpo ti Àjàṣé-ìpo, Olómù ti Òmù-Àrán.

Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun: Ọ̀ọ̀ni tie Ilé-Ifẹ̀, Ọ̀ràngún ti ilé ìlá, Ọwá ti Iléṣà, Àtáója ti Òsogbo, Tìmì ti Ẹdẹ, Ògìyàn ti Èjìgbò, Olúwòó ti Ìwó, Akìrun ti Ìkìrun, Ẹbùrú ti Ìbá, Ẹ̀fọ̀n


Ìpínlè Ọ̀yọ́:
Aláàfin ti Ọ̀yọ́, Olúbàdàn ti Ìbàdàn, Şọ̀ún ti Ogbómọ̀ṣọ́, Iba ti Kìsí, Ọ̀ńjọ́ ti Òkehò, Ọ̀kẹ̀rẹ̀ ti Sakí, Alépátà ti Ìgbòrò, Aṣẹ̀yìn ti Ìsẹ́yìn.

Ìpínlè Òndó:
Ọsẹmọ̀wé ti Òndó, Dèjì ti Àkúré, Ọwá ti Ìdànre, Ọlọ́wọ̀ ti Ọ̀wọ̀, Olúfọ̀n ti Ifọ́n, Jẹgun ti Ilẹ̀-Olújìí

Ìpínlè Èkìtì:
Ewi ti Adó-Èkìtì, Ẹlẹ́kọ̀lé ti Ìkọ̀lé, Ogoga ti Ìkẹ̀rẹ̀, Olúfàkì ti Ìfàkì, Ọlọ́yẹ́ ti Ọyẹ́, Ajerò ti Ìjerò, Elémùré ti Èmùré-Èkìtì, Alárá ti Arámọkọ-Èkìtì, Alááyé ti Ẹ̀fọ̀n Alààyè Èkìtì, Onígede ti Ìgede-Èkìtì.

Ìpínlè Ògùn:
Aláké ti Ilẹ̀-Ẹ̀gbá, Àwùjalẹ̀ ti Ìjẹ̀bú-Òde, Olú ti Ìlaròó, Alayé ti Ayétòrò, Àkárìgbò ti Rẹ́mọ, Èbùmàwé ti Àgọ́-Ìwọ̀yè, Olúbàrà ti Ìbàrà, Àjàlọ́run ti Ìjẹ̀bú-Ifẹ̀, Olókò ti Ìjẹ̀bú-Mushin, Ọwá obokun ti Ìjẹ̀sà

Ìpínlè Kogi:
Ẹlẹ́gbẹ̀ ti Ẹ̀gbẹ̀, Ọbaró/Ọbadọ̀fin ti Kàbbà, Olú ti Ayétòrò-Gbẹdẹ, Àgbànná ti Ìsànlú-Mọ̀pó, Ẹlẹ́ta ti Ìyàrà, Olúkòyí ti Ìkòyí, Ẹ̀lúlùú ti Mọ̀pà, Olúkìrí ti Kìrí, Eléjìbà of Èjìbà.


Ẹ ṣeun fún ìfẹ́ sí Àṣà àti ẹwà èdè Yorùbá tí ẹ ní.

Àkójọpọ̀ rẹ wáyé láti owó,
AYANWUYI, Israel Temitope
Pẹ̀lú ikọ̀ AIF MEDIA nínú ẹ̀ka wọn tí Yorùbá_dùn_lÉdè
First edition 2013, Newly edited 2018. 

2 comments:

  1. ADE LAFIN MO OBA LOOOTO ILEKE NA SI LAFI N MO AWON IJOYE IRO TOUN TI IPELE TI OYATO LAFI N MO AWON IYALODE ,
    WAYI O EDE TO PEREGEDE LAFI N MO AWON ENI TO MO EDE PE LASIKO TI WON BA N FI EDE DARA TO PEREGEDE

    Ayanwuyi Isreal Temitope
    Oni yowo bi aso olowo pooku
    IRE OOO

    ReplyDelete
  2. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún àyẹ́sí yìí

    ReplyDelete

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA