ÀRÒGÚN: ÀWÍJÀRE
ÀRÒGÚN: ÀWÍJÀRE
Láti ọwọ́ Israel Ayanwuyi
Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú orílẹ̀-èdè kan tàbí ìrètí ọjọ́ ọ̀la tó dára àgbáyé, ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ló yẹ ká kọ́kọ́ mú gbọ́, nítorí ení là á ṣe kátó ṣ'èjì ló dífá fún àpọ́n tí ń fi ojoojúmọ́ ṣe ìdárò ọmọ—Ẹni tó bá máa bímọ, ọ̀rọ̀ ìyàwó ló yẹ kó kọ́kọ́ mú gbọ́.
Láti inú ìdílé ni ọmọ tí ń wá, ìdí nìyí tí gbogbo ẹni tó ń gbèrò à ti ní ìdílé pẹ̀lú àwọn tó ní ìdílé lọ́wọ́ báyìí fi gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run yó ṣe fi ore-ọ̀fẹ́ fún wọn láti jẹ́ òbí tó kún ójú òṣùwọ̀n.
Ọ̀rọ̀ ìyàwó tàbí ọkọ níní kì í kàn ṣe ti ọjọ́ orí, àgbà kò kọgbọ́n; kì í ṣe mo ti n'íṣẹ́ lápá tàbí owó lọ́wọ́, owó lásán kọ́ni wọ́n fí t'ọ́mọ yanjú; kì í ṣe mo ti parí ilé-ìwé, iṣẹ́ ni ìdílé, kì í ṣe yàrá ì fi sàtífíkétì ilé-ìwé yangàn.
Ǹ jẹ́ mo ti ṣetán àti ní sùúrù; nífẹ̀ẹ́ àìlódiwọ̀n sí ẹnìkejì mi; darí àwọn ènìyàn mi nínú ìfẹ́ lójú ìpènijà; lọ́ ìdílé mi sórí àpáta kí ìjì, ìkún-omi tàbí ìpọ́njú ńlá ayé má ba à gbé lọ? Ìbéèrè pàtàkì wọ̀nyí àti àwọn míràn ló yẹ kó o bi ara rẹ kí o tó gbé ìyàwó tàbí lọ́kọ. Àìní òye bí ìdílé ṣe ń ṣiṣẹ́ ló máa ń padà fàbọ̀ s'órí àwọn ọmọ nítorí kòní sí ìtọ́ni tó gbọn-n-gbọ́n fún wọn.
Bí a bá wo ọ̀rọ̀ yí dáadáa, ọ̀rọ̀ tó fa kíki ni. Ṣé ti ìṣekú pa ara ẹni tó ń jà rà-ìn-rà-ìn kárí ọ̀pọ̀ àwùjọ ni káwí ni tàbí ti ìwà ìbàjẹ́ tí ń fi ìgbà-dé-gbà peléke l'órílẹ̀-èdè àgbáyé? Kàkà kí ewé àgbọn dẹ̀, ní se ló ń gbogbò sí i. Ìbànújẹ́ wá dórí àgbà kodò, bẹ́ẹ̀ wọ́n ni àgbà kì í wà lọ́jà k'órí ọmọ tuntun wọ́. Orí ọmọ tuntun ti ìran ìkẹyìn ń wọ́ lọ báì—Ọ̀pẹ̀rẹ̀kẹ́tẹ̀ rẹ̀ ń dàgbà, inú adámọ̀ rẹ̀ sì ń bàjẹ́.
Lọ́jọ́ ọjọ́sí ọmọdé kì í gbójú sókè wo àgbà, bí (àwọn) àgbà bá ń sọ̀rọ̀, àwọn ọmọdé ma ń pa lọ́lọ́ ni ṣùgbọ́n ní ìṣẹ̀yín-ín ohun gbogbo ló ti yí padà. Ìdí tí mo ṣe mú àrògún àsínilétí yìí wá gan ni kí gbogbo wa ó ṣe akitiyan à ti wá ìlọsíwájú òhun ìdàgbàsókè tó mọ́yán lórí fún àwọn ògo wẹ́wẹ́ wa.
Ẹ̀kọ́ ilé gbogbo àti ti bí a ṣe ń gbélé ayé ní gúnmọ́, ìlanilọ́yẹ̀ tó yanjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìtùnú pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára ṣe kókó fún wọn nítorí ọjọ́ ọ̀la kàn kò sí tí a bá tí kó ilà àwọn ọmọ wọ̀nyí kúrò lékọ. Ẹ jẹ́ k'ápawọ́pọ́ pèsè ìrètí-ayọ̀, ìdílé tó ń fi ni lọ́kàn balẹ̀ àti fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn kí ìbànújẹ́ má baà á ráyè débi pé èrò à ti hùwà burúkú àbí pokùnso yò jinlẹ̀ lọ́kàn onírúurú wọn.
Ohun tí ẹyẹ bájẹ ni yóò gbé fò: Ọ̀rọ̀ ìyè àti ìrètí ṣe kókó. Ẹ má jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa ba ẹnikẹ́ni nínú jẹ́ nítorí ìgbà kan ò lọ bí ò réré, ilé ayé kò tẹ́ lọ bí ọ̀pá ìbọn; ọba mẹ́wàá, ìgbà mẹ́wàá lọ̀rọ̀ ilé ayé.
Àgbà kò sí nílùú ìlú bàjẹ́, baálé ilé kú ilé dahoro. A kì í torí àwíjàre kí'tọ́ ó tán lẹ́nu; bẹ́ẹ̀ni, ọ̀rọ̀ ṣókí ti tó fún àgbà tó l'ọ́gbọ́n lórí. Ẹtún ìlú tò ọjọ́ ń lọ. ̀
Àgbà wa kò ní dàgbà ìyà, ẹnu wa yó sì tó ọ̀rọ̀ láwùjọ láṣẹ Adédàá. (Àṣẹ).
Ṣíṣe Ìgbéga Ogún Dáradára Yorùbá Ló Jẹ Wá Lógún
AIF MEDIA | YÒRÙBÁ DÙN LÉDÈ
26052019
© Israel Ayanwuyi, 2019
0 comments:
Post a Comment