Ìtàn d'òwe - Arígbàjá òkò, Ìyàwó ń jà l'Ọ́jà, orogún ń dígbá nílé.


Nígbà kan rí nílùú kan tí ń jẹ́ òkò, àwọn ọkọ àti ìyàwó méjì kàn wà níbẹ̀ tí iṣẹ́ ọkùnrin náà sí ì jẹ́ Àgbẹ-à-roko-bódún-dé.

Ìyáálé jẹ́ oníwà tútù, tí Ìyàwó sì jẹ́ aláápọn ẹ̀dá tí orúkọ rẹ̀ a sì maa jẹ́ Arígbàjá.
Ìyàwó má ń dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ láàrin òun àti Ìyáálé rẹ̀. Arígbàjá kí ì fi Ìyáálé rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀.

Ìwà yii sú ọkọ àti aládùgbó wọn. Èyí ló mú ọkọ tọ àwon Àgbà ìlú lọ torí tí ọ̀rọ̀ bá kàn-kè tó kan-lẹ̀ ó ní bi tí àwọn àgbà ń gbé sí. Bẹ́ẹ̀ni àgbà kìí wà lọ́jà kó rí ọmọ tuntun kó wọ̀.

Àwọn àgbà-à-gbà gbàá ní ìmọ̀ràn pé, tí Ìyàwó bá lọ sí ọjà kí ìyáálé wà nílé.Tí ìyáálé bá sì ri pé àkókò ọjà ti parí kí ó gbé igbá rẹ̀ kí ó kiri lọ.
Ìyáálé ń tèlé ìmọ̀ràn yí. Ìyàwó wá wòye wípé ìyáálé òun kòsí nílé mọ́, nígbà tí òun bá wà nílé. Èyí mú-u pe ọkọ àti ìyáálé rẹ̀ sí àkíyèsí òrò yìí.

Baálé wọn wá fèsì wi pé sé àìrí ìyáálé rẹ̀ nílé ní ń fa ìyọnu báyìí.
Ìyàwó (èyun-un Arígbàjá) wá dáhùn pé òun ò rí ìyáálé òun mọ́ ni kò jẹ́ kí inú òun dùn. Ọkọ dáhùn pé nítorí ìjàngbọ̀n rẹ̀ ni, Arígbàjá bú sẹ́ kún nígbà tí àbùkù ti wọ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Láti odún náà ni òwe yìí ti jẹyọ pé, ARÍGBÀJÁ ÒKÒ, ÌYÀWÓ Ń JÀ LỌ́JÀ, OROGÚN Ń DÍGBÁ NÍLÉ.

Ekú ojú lọ́nà ìtàn tó di gbajúmọ̀ òwe mìíràn tó ń bọ̀ lọ́nà.

Ìwúlò pẹ̀lú àti lo òwe yìí.

As we can see from the story, ARÍGBÀJÁ is a very stubborn person - That causes trouble every now and then.

Thus, this proverb is mainly recited for someone who is a trouble maker or trying to play a rival game, even a competition in something or to make achievement, with his or her counterpart in something. This proverb can adjacently be related to 'Ojú ọrùn tó ẹyẹ fò láì f'ara kan ara wọn'.

'The sky is enough for the bird to fly without touching another.'

Have a better approach to issues with this proverb. It will help you to say your mind very well by saving you a lot of story and explanation.

#Yorùbá dùn l'édè

Àkójọpọ̀ rẹ̀ láti owó - 
Ayanwuyi, Israel Temitope
Pẹ̀lú AIF MEDIA TEAM

0 comments:

Post a Comment

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA