Ìtànd'òwe - Ọwọ́ ọmọdé ò tó pẹpẹ, tàgbàlagbà ò wọ akèrègbè.
- On Monday, April 23, 2018
- No Comment
Tàbí-ṣùgbọ́n kò sí wípé ìtàn d'òwe ni 'Ọwọ́ Ọmọdé ò tó pẹpẹ t'àgbàlagbà ò wọ akèrègbè.
Àmọ́ inú ẹsẹ̀ ifá gan-an ni ìtàn yí ti wáyé.
Ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ báyìí - Ìwórí Méjì
Ọwọ́ èwe ò tó pẹpẹ;
Ti àgbàlagbà ò wo akèrègbè
Iṣé tí èwe bẹ àgbà
Kí ó má ṣe kọ̀mọ́;
Torí gbogbo wa ni a níṣé a jọ ń bẹ ra wa.
Ṣùgbọ́n ìtàn tó jẹ́ ìpìlẹ̀ òwe yìí ló báyìí ;
Alájàpá ni Ìyá Àkànjí, àtọ̀jà kan dé òmíràn sì ni ó máa ńra ọjà. Bí ó bá ná Akẹ̀sán lónìí, yóò ná Ìgbájọ lọ́la.
Ní ọjọ́ kan, Ìyá Àkànjí kíyèsí pé ewúrẹ́ kan máa da oúnjẹ Àkànjí láàmú ní ibi tí ó ma ń gbé si, ni Ìyá Àkànjí bá yáa dọ́gbọ́n si. Kò gbé oúnjẹ Àkànjí sí inú apẹ̀rẹ̀ tí ó máa n gbé sí tẹ́lẹ̀ látàrí ìbẹ̀rù ewúrẹ́ ni ó bá nawọ́ gbé oúnjẹ sórí pẹpẹ kẹ́nu ẹran ó má baà to, ó sì bá ọrọ̀ ajé tirẹ̀ lọ.
Ẹlẹ́gbẹ́ pé ebi ló lé Àkànjí wọlé láti ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni, agbára káká ni ó fi bọ́ aṣọ silẹ̀ kí ó tó máa wá oúnjẹ ọ̀sán rẹ̀ kiri inú ilé nígbà tí kò ri nínú apẹ̀rẹ̀ tí Ìyá rẹ̀ ma ń bá a gbé oúnjẹ sí. Ibi tí ó ti banújẹ́ ni ó ti tajú kán rí abọ́ oúnjẹ rẹ̀ lórí pẹpẹ wọn. Ó wá ku bí yóò ṣe gbé. Orí ìrònú bí yóò ti rí i gbé ló wà tí o fi bọ́ sí ẹ̀dẹ̀-òde ṣùgbọ́n ó wá rí bàbá àgbà tó ń gba atẹgùn.
Ó dọ̀bálẹ̀ kí bàbá, ó wá bẹ bàbá láti jọ̀wọ́ bá òun náwọ́ gbé oúnjẹ òun lórí pẹpẹ. Bàbá ní ìwà àrífín ló wù. Ọmọdé kìí bẹ àgbà níṣẹ́ Àkànjí tọrọ àforíjìn, ó sì gbé àpótí tisẹ̀ láti gbé oúnjẹ rẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà tí ó jẹun tán ni bàbá bá pè é pé kí ó dákun bá òun yọ èso oóyó nínú akèrègbè nítorí pé ẹnu akèrègbè náà kéré fún ọwọ́ òun. Àkànjí dáhùn wípé kí bàbá má bínú wí pé òun kò ní le bà wọn kọwọ́ bọ akèrègbè. Bàbá bá dìde, ó já ọré láti na Àkànjí fún pé ó kọ isé tí òun bẹ Àkànjí. Àkànjí sá bó sí àárín abà kí ẹgba bàbá ó má baà ba.
Bàbá Àkànní tí ó rí wọn ni ó wá dá sí ọ̀rọ̀ náà wí pé; "Bí ẹ bá na ọmọdé yìí, ẹ kàn fàgbà rẹ́ ẹ jẹ lásán ni, nítorí pé gbogbo wa la jọ ń wúlò fún ara wa. Ọmọ bẹ̀ yín nísẹ́ ẹ kọ̀, ẹ wá ní kọ́mọ̀ ó fi tipátipá ṣe iṣé fún yín, kò ṣeé ṣe nítorí oníkálukú ló ní ìwúlò lára, bọ́ wọ́ Àkànjí ò ṣe tó pẹpẹ náà ni tiyín náà ò wọnú akèrègbè."
Bàbá àgbà gba àṣìṣe rẹ̀, wọn sì fé kí ẹlòmíràn ó kọ́gbọ́n nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọn fi sọ ó di òwe wí pé; ỌWỌ́ ỌMỌDÉ Ò TÓ PẸPẸ, TÀGBÀLAGBÀ Ò WỌ AKÈRÈGBÈ.
Ìran ara ẹni lọ́wọ́ ṣe pàtàkì nílẹ̀ Yorùbá, Kágbà ó ran ọmọdé lọ́wọ́, k'ọ́mọdé náà ó siṣé fágbà ni ayé ṣe le gún-régé fún gbogbo wa.
Àkójọpọ̀ rẹ wáyé láti owó,
AYANWUYI, Israel Temitope
Pẹ̀lú ikọ̀ AIF MEDIA nínú ẹ̀ka wọn ti,
#Yorùbá_dùn_lÉdè.
0 comments:
Post a Comment