Yorùbá Ẹ Ronú

 
Bí agbọ́n-ni ti ń wó lé Ẹja,
Tí àpajùbà sì ńba ilé Àparò jẹ́

Èyí ló dífá fún ọmọ Yorùbá àtàtà tó gbàgbé ÀSÀ àti ÌṣE  ilẹ̀ yoòbá

Tó wá ńwí wátà l'Édè

Tó nfojoojúmọ́ wá ìmọ̀ kíkún nípa ẹ̀kọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì
Tó ń mú àmúlù-mọ́là Èdè
Tó pààrọ̀ èdè (ìs'ọ̀rọ̀) bí olè tí ńgba fèrèsé ilé kan bọ́sí òmíràn

Ẹbámi wí fún won pé;
Ebi ọjọ́ alé ní p'arú won.

Ọmọ tó gbàgbé ilé, so àpò ìyà kọ́ọ́
Àti wípé ọmọ tí a ò kọ́ ni yóò gbé ilé tí a kọ́ tà lẹ́yìn ọ̀la

Sébì Olówó wa jẹun yó tán, ikú ló nlé kiri
Ìrẹ̀ jẹun yó tán, ó nwa békùn-békùn kiri

Ohun ìtìjú nipé àwa ọmọ Yorùbá yó tán,à ń pe ìbílẹ̀ àti ohun àdáyé-bá wa ní òfútù-fẹ́tẹ̀



"A language that is not usually use will run into extinction..." 



Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lóti ẹ̀ ti gbà wípé, ẹni bá le sọ Èdè gẹ̀ẹ́sì jẹ́ ọlọgbọ́n àti ènìyàn nlá láwùjọ

Ìrònú àti ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa nipé ẹni bá le sọ Èdé gẹ̀ẹ́sì jé olúwa àti alágbára

Ati-gbàgbé wipé Èdè lásán ni gẹ̀ẹ́sì kìí se òṣùwọ̀n fún ọpọlọ (Ọgbọ́n) tó níláarí tó'sé darí ìlú pẹ̀lú àwùjọ.


Olóòótọ́ ni amọ ìran Yorùbá ìpìlẹ̀ àti ọmọ Òduà tó 'dán-gá-jía' sí láti ìgbà àwọn Baba-nlá-baba wa

Ìdálùú ni iṣẹ́ ìlú

Ọmọ Yorùbá àtàtà kì í ṣe  ohun kan láse patì
Ìran Yorùbá má nse gbogbo ohun tí wón bá dáwọ́lẹ́ yọrí ní

Yorùbá ẹ ronú ;
Ìjìnlẹ̀ ọmọ yoòbá kìí jin akẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ̀'sẹ̀
Inú kan la fí ńbarawa lò papọ̀.

Akì jẹ isu lébù tán kátún máa rétí rẹ̀ lọ́dún tí nbọ̀

Tójú ìwà ọmọlúàbí rẹ
Gba ọ̀nà àtúnbí yẹn
Mójútó ohun ogún ìbí rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ yoòbá ,
Máse jẹ́kí Ohun táa jogún bá di tọ́rọ́-fón-ká
Ìgbẹ̀yìn ni ẹ rò......

Ìwà oníwà lá nwù kiri
Àsà àti ìṣe òkèrè là nlò
....nikò jẹ́kí ayé kó gún-ré-gé fún wa

Bí Oya ńkọ́ lọ́rùn , bí Sàngó ńjó láyé ,kò níí burú fún bàbá kóní ódi ọwọ́ ọmọ òun lọ́rùn

Nínú ìpọ́njú,nínú ìsòro ọmọ Oòduà àtàtà kìí yẹ̀yẹ́ ara wọn
Ìṣọ̀kan won kìí ní ẹlẹ́gbẹ́
À ì lásọ̀ lọ́rùn paàká ọmọ yoòbá kan,ó tó ohun àpérò ọmọ Olúwo gbogbo wọn.

Yorùbá ẹ ronú

Ojú ẹkùn iná, ẹ̀yìn ẹkùn oòrùn.
A kì í dúró kí wọ́n ní Ifẹ̀ ọọ̀ni
Ẹnìkan kì í bẹ̀rẹ̀ kíwọn ní Ifẹ̀ oòyè
Òní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ni a mọ ìran Yorùbá sí
Ìkíni àti ìṣòrọ̀-sí tó ń fí ọ̀yàyà pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn wọn hàn òní ẹlẹ́gbẹ́

Yorùbá loní ká júbà ara wọn pẹ̀lú inú kan.

Inú bíbí kò da ǹkan fún ni, sùúrù ní baba ìwà
Àgbà tó ní sùúrù ohun gbogbo loní.
Pẹ̀lẹ́ kùsù ní Yorùbá fí ńṣe ǹkan tiwọn
Ilé ayé asán àdì mọ àyà, sùúrù àti Ìtẹ́lọ́rùn ló ṣe pàtàkì jù.

Orí dífá orí gba adé : ọrùn dífá ọrùn gba òjìgbàrà ìlẹ̀kẹ̀,
Bèbè ìdí dífá ó gba mọ́sàajì aṣọ ọba tí í tanná yanran-yanran

Máse gbàgbé orísun rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ Odùduwà,
Kí o mọ baà sunkún ọjọ́ alẹ́.


Ọmọ àlè níí fí ọ́wọ́ òsì júwe ilé bàbá rẹ̀


I hope you will be glad to join a trend AIF MEDIA organized on WhatsApp Group called Yorùbá Lifestyle Facts Conference.
You deserve to know better about the real Africa they don't show you!


   Israel Ayanwuyi
      9/7/2017
   Contact us on WhatsApp directly

0 comments:

Post a Comment

About Us

AIF MEDIA is where we tune lives with tongue and culture. AIF MEDIA is a medium with passion to unite Yorùbá people to their heritage; promote and preserve godly virtues from Yorùbá culture, tradition and lifestyle; and give poetic admonitions.

Our Networks:
YorùbáDùnlÉdè | Ìtumọ̀ | Biblicopoetry

Contact Info

Email: ayanwuyiisrael@gmail.com

Phone: +234 7032932463

Address: Àyọkà Road, Round-About Area, Ògbómọ̀ṣọ́, Ọ̀yọ́ State

YouTube: AIF MEDIA

Facebook, Twitter and Instagram: AIF MEDIA